Olubanisoro se alaye lekunrere ohun ti a npe ni Ojo Ikehin ati awon orisirisi oruko ti Olohun Allah fun un ninu Alukuraani, Olubanisoro si tun se alaye awon nkan ti Ojo Igbehin ko sinu.
1- Ibanisoro yii se afihan orisi ona meta ti Okan pin si, bee si ni Olubanisoro je ki a mo awon orisi arun ti o ma nse Okan. 2- Alaye ni afikun lori okan ti o nse aare ati ohun ti o je iwosan fun un. Iwosan ti o si dara julo ni nini igbagbo ti o peye ninu Olohun Allah ati mima ka Alukurani Alaponle ni gbogbo igba.
Alaye ohun ti o se okunfa ogun yii ati awon isele ti o waye nibi sise ipalemo fun ogun naa eyi ti o je eri ododo lori wipe Annabi Muhammad ojise Olohun ni. Alaye si tun waye lori aranse ti Olohun se fun ojise Re ninu ogun naa.
1- Se awa Musulumi ni eto Kankan lori ile Filistin? Kinni awon igbiyanju ti awon asaaju Musulumi ti se ninu itan lori ile Filistin? Nje awa Musulumi aye ode oni ni igbiyanju kan lati se bi lori ati so ile Filistin di ile ominira fun Musulumi papaajulo masalaasi Kudusi? Gbogbo awon ibeere wonyi ni a o ri idahun fun ninu ibanisoro yi. 2- Apa keji ibanisoro yi so nipa awon ogbon arekereke ti awon Yahudi lo lati fi gba ile Filistin ti won si le awon ti won ni ile kuro, bakannaa ni oro waye lori itumo Yahudi ati ipile gbolohun naa.
Waasi yi so nipa idajo Islam lori orin kiko ati gbigbo. Oniwaasi mu awon eri ti o po wa lati inu Al-kurani ati hadiisi lori bi orin gbigbo ati kiko se je eewo ninu Islam. Bakannaa ni oro waye ninu waasi yi lori awon aburu repete ti o wa nibi gbigbo orin ati kiko.