Oro nipa awon ohun ti a maa nyo Saka ninu won, ati oundiwon ti a o yo ninu awon nkan ti Saka wo, Olubanisoro si bere pelu Aayah Alukuraani ti o nso nipa ijiya ti nbe fun awon ti won maa nko dukia jo laiyo Saka ninu re.
Idanileko yi so alaye gbogbo awon idajo ti o ro mo gbigba iwaju eni ti o ba n ki irun koja, yala eni ti o fi nkan si iwaju re tabi eni ti ko fi nkankan si iwaju.
1- Eleyi ni oro nipa ohun ti o je ojuse Musulumi nibi ibo didi ati idajo Islam lori kikopa ninu idibo. 2- Itesiwaju nipa ohun ti Islam so lori eto oselu tiwa- ntiwa (Demokiresi), olubanisoro menu ba idajo esin lori dida egbe oselu sile ati kikopa ninu re, o si tun so nipa ojuse eniti o ba fe gbegba fun ipo oselu.
Idanileko yi so nipa awon eko ti Islam gbe kale fun eniti o ba ngba aawe gege bii yiyara fun isinu ati lilora lati je saari, bakannaa ni oludanileko tun so oro nipa asiko ti aawe maa nbere ati asiko ti o maa npari, o si tun so nipa bi esin Islam se se aawe agbayipo ni eewo.
Koko idanileko yi ni oro nipa itanran ti o nbe fun eni ti o ni ajosepo pelu eleto re ni osan Ramadan, oniwaasi se alaye re ni ekunrere o si tun menu ba awon idajo miran.
Eleyi ni itumo awon hadiisi kan ti o so nipa sakaatul fitri ti awon Yoruba npe ni jaka. Oniwaasi se alaye awon idajo esin ti o ro mo o gege bii awon ti o ye ki o yo o, irufe ounje ti a fi maa nyo o ati odiwon ti o ye ki a yo.