Idajọ Ẹsin Islam lori Didaabo bo Ẹmi ara ẹni

Olùfèsì si ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn :

Sise ogbifo: Rafiu Adisa Bello

Sise atunyewo: Hamid Yusuf

Ọ̀rọ̀ ṣókí

Alaye lori bi shẹria Islam se daabo bo ẹmin ati ọmọluabi ati laakaye ati owo ati ẹsin.

Download
Ko idasọrọ si alamojuto oju ewe yii

Asọkun ọrọ

    Idajọ Ẹsin Islam lori

    Didaabo bo Ẹmi ara ẹni

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Oju Ewe Ayelujara

    IBEERE ATI IDAHUN NIPA ỌRỌ ẸSIN ISLAM

    Labẹ Amojuto:

    Sheikh Muhammad Sọọlih Al-munajjid

    Itumọ si ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello

    Atunyẹwo : Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    حكم الإسلام في الدفاع عن النفس

    « بلغة اليوربا »

    موقع الإسلام سؤال وجواب

    الشيخ محمد صالح المنجد

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: حامد يوسف

    2015 - 1436

    IBEERE ATI IDAHUN LORI ỌRỌ ẸSIN ISLAM

    FATWA [21932]

    IBEERE:

    Kinni idajọ ẹsin Islam lori didaabo bo ẹmi ara ẹni? Se ninu awọn ẹtọ ni o wa? Se awọn ẹtọ yi si ni majẹmu? Bakanna, se Alukuraani n sọ ọrọ nipa idaabo bo ẹmi ara ẹni?

    ………………………..……………………………….

    IDAHUN:

    Ọpẹ ni fun Ọlọhun.

    Didaabo bo ẹmin ati ọmọluabi ati laakaye ati owo ati ẹsin, gbogbo rẹ wa ninu awọn nkan ti sharia Islam se amojuto rẹ ni dandan. Nitori idi eyi, dandan ni fun eniyan lati sọ ẹmi ara rẹ, ko gbọdọ jẹ tabi mu ohun ti o le ko ipalara ba a, kosi gbọdọ gba ẹnikẹni ni aaye lati se ohun ti o le fa ipalara fun un.

    Ti eniyan kan, tabi ẹranko abija kan, tabi nkan miran ba fẹ se e ni suta, tabi o fẹ se ara ile rẹ ni suta, tabi o fẹ gba owo rẹ, dandan ni fun un lati gba ara rẹ silẹ, ki o si daabo bo ara ile rẹ ati owo rẹ. Ti o ba wa sẹlẹ pe agbara ẹni naa ka a, ti o ba pa a, oju ọna Ọlọhun ni o ku si (o ku iku shẹiidi), ẹniti o si pa a yoo wọ ina gbere ni ọrun.

    Ni afikun, ti o ba jẹ wipe inira ti o jẹyọ lati ibi abosi naa kii se ohun ti o pọ pupọ, ti o si fi ẹniti o se abosi naa silẹ nitori Ọlọhun, ti ko se nkankan fun un, dajudaju Ọlọhun yoo fi ohun ti o loore paarọ fun un, nigbati o ba jẹ wipe kii se oun funra rẹ ni o fi ọwọ ara rẹ fa abosi naa.

    Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan:

    Àwọn ìsọ̀rí ti ìmọ̀: