Se pẹlu agbara ni o yẹ ki a fi bẹrẹ lati se atunse iwa ti ko dara bi?

Olùfèsì si ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn :

Sise ogbifo: Rafiu Adisa Bello

Sise atunyewo: Hamid Yusuf

Ọ̀rọ̀ ṣókí

Idahun lori bi o se jẹ wipe sise ayipada isesi tabi iwa ti ko dara wa ni ipele ipele.

Download
Ko idasọrọ si alamojuto oju ewe yii

Asọkun ọrọ

    Ti a ba se akiyesi iwa tabi isesi ti ko

    dara, se pẹlu agbara ni o yẹ ki

    a fi bẹrẹ lati se atunse rẹ bi?

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Oju Ewe Ayelujara

    IBEERE ATI IDAHUN NIPA ỌRỌ ẸSIN ISLAM

    Labẹ Amojuto:

    Sheikh Muhammad Sọọlih Al-munajjid

    Itumọ si ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello

    Atunyẹwo : Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    هل نبدأ باليد في تغيير المنكر؟

    « بلغة اليوربا »

    موقع الإسلام سؤال وجواب

    الشيخ محمد صالح المنجد

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: حامد يوسف

    2015 - 1436

    IBEERE ATI IDAHUN LORI ỌRỌ ẸSIN ISLAM

    FATWA: [10522]

    IBEERE:

    Ti a ba se akiyesi iwa tabi isesi ti ko dara, se pẹlu agbara ni o yẹ ki a fi bẹrẹ lati se atunse rẹ bi?

    Se itumọ hadiisi ti o sọ wipe: (Ẹniti o ba ri nkan ti ko dara, ki o yii pada pẹlu ọwọ rẹ ……) ni wipe ki a bẹrẹ pẹlu lilo agbara lati yi nkan ti ko dara pada, koda ki o jẹ wipe o rọrun lati yii pada pẹlu ọrọ ẹnu?

    ……………………………………………………………………….

    IDAHUN:

    Ọpẹ ni fun Ọlọhun.

    Sise ayipada isesi tabi iwa ti ko dara wa ni ipele ipele, bẹrẹ lati ipeni si akiyesi ni pẹlẹpẹlẹ ati iran ara ẹni leti, lẹhinnaa sise waasi ati riran ni leti iya Ọlọhun, lẹhinnaa jijagbe mọ ẹni, lẹhinnaa lilo agbara pẹlu fifi iya jẹ'ni. Eyi ti o gbẹyin rẹ naa ni gbigbe ọrọ ẹniti o se aburu naa tabi hu iwa buburu lọ si ọdọ alasẹ, lẹyin ti a ti se gbogbo awọn igbesẹ ti o siwaju ti ko si fi isẹ ọwọ rẹ silẹ.

    Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan:

    Àwọn ìsọ̀rí ti ìmọ̀: